Jeremiah 31:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kì í ṣe irú majẹmu tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá, ní ìgbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ jáde ní ilẹ̀ Ijipti, àní majẹmu mi tí wọn dà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi ni ọkọ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kì iṣe bi majẹmu na ti emi ba baba wọn dá li ọjọ na ti emi fà wọn lọwọ lati mu wọn jade lati ilẹ Egipti: awọn ti nwọn dà majẹmu mi, bi emi tilẹ jẹ alakoso wọn sibẹ, li Oluwa wi;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò ní dàbí májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá, nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́, tí mo mú wọn jáde ní Éjíbítì nítorí wọ́n da májẹ̀mú mi. Lóòótọ́ ọkọ ni èmi jẹ́ fún wọn,” ni OLÚWA wí.