Jeremiah 31:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn majẹmu tí n óo bá ilé Israẹli dá nígbà tó bá yá nìyí: N óo fi òfin mi sí inú wọn, n óo sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn. N óo máa jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì máa jẹ́ eniyan mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn eyi ni majẹmu ti emi o ba ile Israeli da; Lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi, emi o fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ ọ si aiya wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, awọn o si jẹ enia mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ìgbà náà,” ni OLÚWA wí pé: “Èmi yóò fi òfin mi sí ọkàn wọn, èmi ó sì kọ ọ́ sí àyà wọn. Èmi ó jẹ́ OLÚWA wọn; àwọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi.