Jeremiah 31:35 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ni ó dá oòrùn, láti máa ràn ní ọ̀sán, tí ó fún òṣùpá ati ìràwọ̀ láṣẹ, láti tan ìmọ́lẹ̀ lálẹ́, tí ó rú omi òkun sókè, tí ìgbì rẹ̀ ń hó yaya, òun ni orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi ti o fi õrùn fun imọlẹ li ọsan, ilana oṣupa ati irawọ fun imọlẹ li oru, ti o rú okun soke tobẹ̃, ti riru omi rẹ̀ nho; Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: ẹni tí ó mú oòrùn tan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, tí ó mú òṣùpá àti ìràwọ̀ ràn ní òru; tí ó rú omi òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí Ìjì rẹ̀ fi ń hó OLÚWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.