Jeremiah 31:36 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Òun ló sọ pé, àfi bí àwọn àṣẹ wọnyi bá yipada níwájú òun, ni àwọn ọmọ Israẹli kò fi ní máa jẹ́ orílẹ̀-èdè títí lae.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ilana wọnyi ba yẹ̀ kuro niwaju mi, li Oluwa wi, njẹ iru-ọmọ Israeli pẹlu yio dẹkun lati ma jẹ orilẹ-ède niwaju mi lailai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àyàfi tí ìlànà yìí bá kúrò níwájú mi,” ni OLÚWA wí. “Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò dẹ́kun láti jẹ́ orílẹ̀ èdè níwájú mi láéláé.”