Jeremiah 31:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Ẹ kọ orin sókè pẹlu ìdùnnú fún Jakọbu, kí ẹ sì hó fún olórí àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ kéde, ẹ kọ orin ìyìn, kí ẹ sì wí pé, ‘OLUWA ti gba àwọn eniyan rẹ̀ là àní, àwọn eniyan Israẹli yòókù.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa wi; ẹ fi ayọ̀ kọrin didùn fun Jakobu, ẹ si ho niti olori awọn orilẹ-ède: ẹ kede! ẹ yìn, ki ẹ si wipe: Oluwa, gbà awọn enia rẹ la, iyokù Israeli!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ọ̀rọ̀ tí OLÚWA sọ wí pé: “Ẹ fi ayọ̀ Kọrin sí Jákọ́bù; ẹ hó sí olórí àwọn orílẹ̀ èdè gbogbo. Jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìyìn rẹ kí o sì wí pé, ‘OLÚWA, gba àwọn ènìyàn rẹ là; àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Ísírẹ́lì.’