Jeremiah 31:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ wò ó! N óo kó wọn wá láti ilẹ̀ àríwá, n óo kó wọn jọ láti òpin ayé. Àwọn afọ́jú ati arọ yóo wà láàrin wọn, ati aboyún ati àwọn tí wọn ń rọbí lọ́wọ́. Ogunlọ́gọ̀ eniyan ni àwọn tí yóo pada wá síbí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wò o, emi o mu wọn lati ilẹ ariwa wá, emi o si kó wọn jọ lati àgbegbe ilẹ aiye, afọju ati ayarọ pẹlu wọn, aboyun ati ẹniti nrọbi ṣọkan pọ̀: li ẹgbẹ nlanla ni nwọn o pada sibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wò ó, Èmi yóò mú wọn wá láti ilẹ̀ àríwá; èmi yóò kó gbogbo wọn jọ láti òpin ayé. Lára wọn ni yóò jẹ́ afọ́jú àti arọ, aboyún àti obìnrin tí ń rọbí, ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wá.