Jeremiah 31:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Tẹkúntẹkún ni wọn yóo wá, tàánútàánú ni n óo sì fi darí wọn pada. N óo mú kí wọn rìn ní etí odò tí ń ṣàn, lójú ọ̀nà tààrà, níbi tí wọn kò ti ní fẹsẹ̀ kọ; nítorí pé baba ni mo jẹ́ fún Israẹli, àkọ́bí mi sì ni Efuraimu.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o wá pẹlu ẹkun, pẹlu adura li emi o si ṣe amọ̀na wọn: emi o mu wọn rìn lẹba odò omi li ọ̀na ganran, nwọn kì yio kọsẹ ninu rẹ̀: nitori emi jẹ baba fun Israeli, Efraimu si li akọbi mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò wá pẹ̀lú ẹkún, wọn yóò gbàdúrà bí Èmi yóò ṣe mú wọn padà. Èmi yóò jẹ́ atọ́nà fún wọn ní ẹ̀bá odò omi; ní ọ̀nà tí ó tẹ́jú tí wọn kì yóò le ṣubú, nítorí èmi ni baba Ísírẹ́lì, Éfúráímù sì ni àkọ́bí ọkùnrin mi.