Jeremiah 32:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
mo sì fún Baruku ọmọ Neraya ọmọ Mahiseaya ní èyí tí a fi òǹtẹ̀ tẹ̀, níṣojú Hanameli, ọmọ arakunrin baba mi ati níṣojú àwọn ẹlẹ́rìí tí wọn fọwọ́ sí ìwé ilẹ̀ náà, ati níṣojú gbogbo àwọn ará Juda tí wọn jókòó ní àgbàlá àwọn olùṣọ́ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si fi iwe rirà na fun Baruki, ọmọ Neriah, ọmọ Masseiah, li oju Hanameeli, ọmọ ẹ̀gbọn mi, ati niwaju awọn ẹlẹri ti o kọ orukọ wọn si iwe rirà na, niwaju gbogbo ọkunrin Juda ti o joko ni àgbala ile túbu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi sì fi èyí fún Bárúkì ọmọkùnrin ọmọ ẹ̀gbọ́n mi àti níwájú àwọn ẹlẹ́rìí tí ó ti fi ọwọ́ sí ìwé àti ní ojú àwọn Júù gbogbo tí wọ́n jókòó ní àgbàlá túbú.