Jeremiah 32:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ìwọ tí ò ń fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn fún ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, ṣugbọn tí ò ń gba ẹ̀san àwọn baba lára àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn ikú wọn, ìwọ Ọlọrun alágbára ńlá tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ ṣe ãnu fun ẹgbẹgbẹrun, o si san aiṣedede awọn baba si aiya awọn ọmọ lẹhin wọn: Ọlọrun titobi, Alagbara! Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
O fi ìfẹ́ hàn sí ẹgbẹ̀gbẹ̀rún àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n o gbé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba lé àwọn ọmọ lẹ́yìn wọn. Ọlọ́rùn títóbi àti alágbára, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ.