Jeremiah 32:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n dé ilẹ̀ náà, wọ́n sì gbà á; ṣugbọn wọn kò gbọ́rọ̀ sí ọ lẹ́nu, wọn kò sì pa òfin rẹ mọ́. Wọn kò ṣe ọ̀kan kan ninu gbogbo ohun tí o pàṣẹ fún wọn láti máa ṣe; nítorí náà ni o ṣe mú kí gbogbo ibi tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn bá wọn!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wá, nwọn si ni i; ṣugbọn nwọn kò gbà ohùn rẹ gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò rìn ninu ofin rẹ, nwọn kò ṣe gbogbo eyiti iwọ paṣẹ fun wọn lati ṣe: iwọ si pè gbogbo ibi yi wá sori wọn:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n wá, wọ́n sì gba ilẹ̀ náà ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ tàbí tẹ̀lé òfin rẹ. Wọn kò ṣe ohun tí o paláṣẹ fún wọn, nítorí náà ìwọ mú àwọn ibi yìí wá sórí wọn.