Jeremiah 32:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“ ‘Wo bí àwọn ọ̀tá ti mọ òkítì sí ara odi wa láti gba ìlú wa. Nítorí ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn, a óo fi ìlú yìí lé àwọn ará Kalidea tí wọn gbógun tì í lọ́wọ́. Ohun tí o wí ṣẹ, o sì ti rí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wo o! odi ọta! nwọn sunmọ ilu lati kó o; a si fi ilu le ọwọ awọn ara Kaldea, ti mba a jà, niwaju idà, ati ìyan, àjakalẹ-àrun: ati ohun ti iwọ ti sọ, ṣẹ; si wò o, iwọ ri i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Wò ó, bí àwọn ìdọ̀tí ṣe korájọ láti gba ìlú. Nítorí idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn, sì fi ìlú lé ọwọ́ àwọn ará Kálídéà tí ń gbógun tì wọ́n. Ohun tí ìwọ sọ ṣẹ gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i.