Jeremiah 32:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ará Kalidea tí wọn gbógun ti ìlú yìí, yóo wọ inú rẹ̀, wọn yóo sì dáná sun ún pẹlu àwọn ilẹ̀ tí wọ́n tí ń sun turari sí oriṣa Baali lórí wọn, tí wọ́n sì tí ń rú ẹbọ ohun mímu sí àwọn oriṣa tí wọn ń mú mi bínú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn ara Kaldea, ti mba ilu yi jà, nwọn o wá, nwọn o si tẹ iná bọ̀ ilu yi, nwọn o si kun u, ati ile, lori orule eyiti nwọn ti nrubọ turari si Baali, ti nwọn si ti ndà ẹbọ ohun mimu fun ọlọrun miran, lati mu mi binu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ará Kálídéà tí ó ń gbógun tí ìlú yóò wọ ìlú. Wọn ó sì fi iná sí ìlú; wọn ó jó o palẹ̀ ní ọ̀nà ilé tí àwọn ènìyàn ti ń mú mi bínú, tí wọ́n ń rúbọ tùràrí lórí pẹpẹ fún Báálì ti wọn sì ń da ẹbọ òróró fún Ọlọ́run mìíràn.