Jeremiah 32:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí láti ìgbà èwe àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn eniyan Juda ni wọ́n tí ń ṣe kìkì nǹkan tí ó burú lójú mi, kìkì nǹkan tí yóo bí mi ninu ni àwọn ọmọ Israẹli náà sì ń ṣe. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori awọn ọmọ Israeli ati awọn ọmọ Juda ti ṣe kiki ibi niwaju mi lati igba èwe wọn wá: nitori awọn ọmọ Israeli ti fi kiki iṣẹ ọwọ wọn mu mi binu, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì àti Júdà kò ṣe ohun kankan bí kò ṣe ibi lójúmi láti ìgbà èwe wọn. Nítorí àwọn ọmọ Isreli ti fi kìkì iṣẹ́ ọwọ́ wọ́n mú mi bínú ni OLÚWA wí