Jeremiah 32:35 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n kọ́ ojúbọ oriṣa tí ó wà ní àfonífojì ọmọ Hinomu láti máa fi àwọn ọmọ wọn, lọkunrin ati lobinrin rú ẹbọ sí oriṣa Moleki, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò pa á láṣẹ fún wọn, tí kò sì wá sí mi lọ́kàn pé wọ́n lè ṣe irú ohun ìríra bẹ́ẹ̀, láti mú Juda dẹ́ṣẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si kọ́ ibi giga Baali, ti o wà ni afonifoji ọmọ Hinnomu, lati fi awọn ọmọkunrin wọn ati awọn ọmọbinrin wọn fun Moleki; ti emi kò paṣẹ fun wọn, bẹ̃ni kò wá si ọkàn mi, pe ki nwọn ki o mã ṣe ohun irira yi, lati mu Juda ṣẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n kọ́ ibi gíga fún Báálì ní àfonífojì Hínómù láti fi ọmọ wọn ọkùnrin àti obìnrin rúbọ sí Mólékì. Èmi kò páláṣẹ, fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò wá sí ọkàn mi pé kí wọ́n ṣe ohun ìríra wọ̀nyí tí ó sì mú Júdà ṣe.