Jeremiah 32:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ati pé Sedekaya ọba Juda kò ní bọ́ lọ́wọ́ àwọn ará Kalidea. Ó ní Jeremaya sọ pé dájúdájú, OLUWA óo fi òun Sedekaya lé ọba Babiloni lọ́wọ́, àwọn yóo rí ara àwọn lojukooju, àwọn yóo sì bá ara àwọn sọ̀rọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati Sedekiah, ọba Juda, kì yio bọ́ li ọwọ awọn ara Kaldea, ṣugbọn a o fi i le ọwọ ọba Babeli, Lõtọ, yio si ba a sọ̀rọ li ojukoju, oju rẹ̀ yio si ri oju rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sedekáyà Ọba Júdà kò lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn Kálídéà, ṣùgbọ́n à ó mú fún Ọba Bábílónì, yóò sì bá sọ̀rọ̀ ní ojúkojú; yóò sì rí pẹ̀lú ojú rẹ̀.