Jeremiah 32:42 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Bí mo ṣe mú gbogbo ibi ńlá yìí bá àwọn eniyan wọnyi, bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe mú kí gbogbo ohun rere tí mo ti ṣe ìlérí fún wọn dé bá wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa wi; Gẹgẹ bi emi ti mu gbogbo ibi nla yi wá sori awọn enia yi, bẹ̃ni emi o mu gbogbo rere ti emi ti sọ nipa ti wọn wá sori wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí bayìí ni OLÚWA wí: Gẹ́gẹ́ bí èmi ti mú gbogbo ibi ńlá yìí wá sórí àwọn ènìyàn yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó mú gbogbo rere tí èmi ti sọ nípa ti wọn wá sórí wọn.