Jeremiah 32:44 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn yóo máa fi owó ra oko, wọn yóo máa ṣe ìwé ilẹ̀, wọn yóo máa fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ẹ́; wọn yóo máa fi èdìdì dì í, àwọn ẹlẹ́rìí yóo sì máa fi ọwọ́ sí i, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa rí ní ilẹ̀ Bẹnjamini. Nígbà tí mo bá dá ire wọn pada, ati ní àwọn agbègbè Jerusalẹmu, ní àwọn ìlú Juda, ati àwọn ìlú agbègbè olókè, ní àwọn ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣefela, ati àwọn ìlú ilẹ̀ Nẹgẹbu. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Enia yio fi owo rà oko, nwọn o kọ ọ sinu iwe, nwọn o si dí i, nwọn o si pe awọn ẹlẹri ni ilẹ Benjamini, ati ni ibi wọnni yi Jerusalemu ka, ati ni ilu Juda, ati ni ilu ọwọ́-oke na, ati ni ilu afonifoji, ati ni ilu iha gusu; nitori emi o mu igbekun wọn pada wá, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn ó fi owó fàdákà ra oko, wọn yóò fi ọwọ́ sí ìwé, wọn ó dí i pa pẹ̀lú ẹlẹ́rìí láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì àti ní ìlú kékèké tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká àti ní ìlú Júdà àti ní ìlú ọwọ́ òkè orílẹ̀ èdè ní ìhà gúṣù olókè ilẹ̀ àti ní Gúsù, nítorí èmi ó mú ìgbékùn wọn padà wá, ni OLÚWA wí.”