Jeremiah 32:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
‘Hanameli ọmọ Ṣalumu, arakunrin baba rẹ, yóo wá bá ọ pé kí o ra oko òun tí ó wà ní Anatoti, nítorí pé ìwọ ni ó tọ́ sí láti rà á pada.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wò o, Hanameeli, ọmọ Ṣallumu, ẹ̀gbọn rẹ, yio tọ̀ ọ wá, wipe, Iwọ rà oko mi ti o wà ni Anatoti: nitori titọ́ irasilẹ jẹ tirẹ lati rà a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Hánámélì ọmọkùnrin Sálúmù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yóò tọ̀ ọ́ wá pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní Ánátótì; nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹni tó sún mọ́ wọn, ẹ̀tọ́ àti ìṣe rẹ ní láti rà á.’