Jeremiah 32:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà Hanameli ọmọ arakunrin baba mi tọ̀ mí wá sí àgbàlá àwọn olùṣọ́ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ, ó sì wí fún mi pé, ‘Jọ̀wọ́ ra oko mi tí ó wà ní Anatoti ní ilẹ̀ Bẹnjamini, nítorí pé ìwọ ni ó tọ́ sí láti rà á pada; rà á fún ara rẹ.’ “Nígbà náà ni mo wá mọ̀ pé àṣẹ OLUWA ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hanameeli, ọmọ ẹ̀gbọn mi, si tọ̀ mi wá li agbala ile túbu gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, o si wi fun mi pe, Jọ̃, ra oko mi, ti o wà ni Anatoti, ti o wà ni ilẹ Benjamini: nitori titọ́ ogun rẹ̀ jẹ tirẹ, ati irasilẹ jẹ tirẹ; rà a fun ara rẹ. Nigbana ni mo mọ̀ pe, eyi li ọ̀rọ Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti sọ, ọmọ ẹ̀gbọ́n mi tọ̀ mí wá ní àgbàlá túbú wí pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní Ánátótì tí ó wà ní ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì, èyí tí ó jẹ́ pé ẹ̀tọ́ rẹ ni láti gbà á àti láti ni, rà á fún ara rẹ.’ “Nígbà náà ni èmi mọ̀ wí pé ọ̀rọ̀ OLÚWA ni èyí.