Jeremiah 33:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní, “A óo tún gbọ́ ohùn ayọ̀ ati inú dídùn ninu ìlú Juda ati ìgboro Jerusalẹmu, tí ẹ sọ wí pé ó ti di ahoro, tí kò sí eniyan tabi ẹranko tó ń gbé inú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi; A o si tun gbọ́ ni ibi yi ti ẹnyin wipe, O dahoro, laini enia ati laini ẹran, ani ni ilu Juda, ati ni ilu Jerusalemu, ti o dahoro, laini enia, ati laini olugbe, ati laini ẹran.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí ni ohun tí OLÚWA sọ nípa ti ilẹ̀ yìí pé ó dahoro láìsí ọkùnrin àti àwọn ẹran. Síbẹ̀ ní ìlú Júdà ní pópónà ti Jérúsálẹ́mù tí ó di àkọsílẹ̀ láìsí ẹni tó gbé ibẹ̀; yálà ní ọkùnrin tàbí àwọn ẹran, wọn ó gbọ́ lẹ́ẹ̀kan sí.