Jeremiah 33:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
A óo tún gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ohùn iyawo ati ohùn àwọn tí wọn ń kọrin bí wọ́n ti ń mú ẹbọ ọpẹ́ wá sinu ilé OLUWA wí pé: 107:1; 118:1; 136:1 ‘Ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA àwọn ọmọ ogun, nítorí pé rere ni OLUWA, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae!’ Nítorí pé n óo dá ire wọn pada bíi ti ìgbà àtijọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ohùn ayọ̀, ati ohùn inu-didùn, ohùn ọkọ-iyawo, ati ohùn iyawo, ohùn awọn ti o wipe, Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa awọn ọmọ-ogun: nitori ti o ṣeun, nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai: ati ti awọn ti o mu ẹbọ-ọpẹ́ wá si ile Oluwa. Nitoriti emi o mu igbèkun ilẹ na pada wá gẹgẹ bi atetekọṣe, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ariwo di ayọ̀ àti inú dídùn, ohùn ìyàwó àti ti ọkọ ìyàwó àti ohùn àwọn tí ó ru ẹbọ ọpẹ́ wọn nílé OLÚWA wí pé: “Yin OLÚWA àwọn ọmọ ogun, nítorí OLÚWA dára, ìfẹ́ rẹ̀ dúró títí láéláé.” Nítorí èmi ó dá ìkólọ ilẹ̀ náà padà sí bí o ṣe wà tẹ́lẹ̀ ni OLÚWA wí: