Jeremiah 33:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ pé, “Ní gbogbo ibi tí ó ti di ahoro yìí, tí eniyan tabi ẹranko kò gbé ibẹ̀, àwọn olùṣọ́-aguntan yóo sì tún máa tọ́jú àwọn agbo ẹran wọn ninu gbogbo àwọn ìlú ibẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe; Papa-oko awọn oluṣọ-agutan yio tun wà, ti nwọn mu ẹran-ọsin dubulẹ ni ibi yi, ti o dahoro, laini enia ati laini ẹran, ati ni gbogbo ilu rẹ̀!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí, ‘Ní ilẹ̀ yìí tí ó ti dahoro láìsí ọkùnrin àti àwọn ẹran nínú gbogbo ìlú, kò ní sí pápá oko fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn láti mú àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sinmi.