Jeremiah 33:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn agbo ẹran yóo tún kọjá níwájú ẹni tí ó ń kà wọ́n ninu àwọn ìlú tí wọ́n wà ní agbègbè olókè, ati àwọn ti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣefela ati àwọn ìlú tí wọn wà ní Nẹgẹbu, ní ilẹ̀ Bẹnjamini, ní agbègbè tí ó yí Jerusalẹmu ká, ati àwọn ìlú Juda. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu ilu oke wọnni, ninu ilu afonifoji, ati ninu ilu iha gusu, ati ni ilẹ Benjamini, ati ni ibi wọnni yi Jerusalemu ka, ati ni ilu Juda ni agbo agutan yio ma kọja labẹ ọwọ ẹniti nkà wọn, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìlú orílẹ̀ èdè òkè wọn, ní ìhà gúṣù ilẹ̀ olókè ní ilẹ̀ ti Bẹ́ńjámínì ní ibi wọ̀n-ọn-nì tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká àti ní ìlú Júdà ni agbo yóò tún máa kọjá ní ọwọ́ ẹni tí ń kà wọ́n,’ ni OLÚWA wí.