Jeremiah 33:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní sí ìgbà kan tí ẹnìkan ninu àwọn alufaa, ọmọ Lefi, kò ní máa dúró níwájú òun láti rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ, láti máa rú ẹbọ títí lae.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, kì yio fẹ ọkunrin kan kù niwaju mi lati ru ẹbọ sisun, ati lati dana ọrẹ ohun jijẹ, ati lati ṣe irubọ lojojumọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà tí ó jẹ́ ọmọ Léfì kò ní kùnà láti ní ọkùnrin kan tí ó dúró níwájú mi ní gbogbo ìgbà láti rú ẹbọ sísun; ẹbọ jíjẹ àti láti pèsè ìrúbọ.’ ”