Jeremiah 33:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
òun nìkan ni majẹmu tí mo bá Dafidi iranṣẹ mi dá ṣe lè yẹ̀, tí ìdílé rẹ̀ kò fi ní máa ní ọmọkunrin kan tí yóo jọba; bẹ́ẹ̀ náà ni majẹmu tí mo bá àwọn alufaa, ọmọ Lefi iranṣẹ mi dá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni majẹmu mi pẹlu Dafidi, iranṣẹ mi le bajẹ, pe ki on ki o má le ni ọmọ lati joko lori itẹ rẹ̀; ati pẹlu awọn ọmọ Lefi, awọn alufa, awọn iranṣẹ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú Léfì tí ó jẹ́ àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ níwájú mi lè bàjẹ́, tí Dáfídì kò sì rí ẹni láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀.