Jeremiah 33:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ṣé o kò gbọ́ ohun tí àwọn eniyan wọnyi ń sọ tí wọn ní, ‘OLUWA ti kọ ìdílé mejeeji tí ó yàn sílẹ̀?’ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń fojú tẹmbẹlu àwọn eniyan mi, títí tí wọn kò fi dàbí orílẹ̀-èdè lójú wọn mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ kò ha ro eyi ti awọn enia yi ti sọ wipe, Idile meji ti Oluwa ti yàn, o ti kọ̀ wọn silẹ̀? nitorina ni nwọn ti ṣe kẹgan awọn enia mi, pe nwọn kì o le jẹ orilẹ-ède kan mọ li oju wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ǹjẹ́ ìwọ kò kíyèsí pé àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń sọ pé: ‘OLÚWA ti kọ àwọn Ọba méjèèjì tí ó yàn sílẹ̀’? Nítorí náà, ni wọ́n ti ṣe kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi. Wọn kò sì mọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè kan.