Jeremiah 33:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
òun nìkan ni n óo fi kọ arọmọdọmọ Jakọbu ati Dafidi, iranṣẹ mi sílẹ̀, tí n kò fi ní máa yan ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ láti jọba lórí ìran Abrahamu, Isaaki ati Jakọbu. N óo dá ire wọn pada, n óo sì ṣàánú fún wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni emi iba ta iru-ọmọ Jakobu nù, ati Dafidi, iranṣẹ mi, ti emi kì o fi mu ninu iru-ọmọ rẹ̀ lati ṣe alakoso lori iru-ọmọ Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu: nitori emi o mu ki igbekun wọn ki o pada bọ̀, emi o si ṣãnu fun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni èmi ó kọ ọmọlẹ́yìn Jákọ́bù àti Dáfídì ìránṣẹ́ mi tí èmi kò sì ní yan ọ̀kan nínú ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ́ alákóso lórí àwọn ọmọlẹ́yìn Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù; nítorí èmi ó mú ìkólọ wọn padà; èmi ó sì ṣàánú fún wọn.’ ”