Jeremiah 34:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọkunrin tí wọn bá rú òfin mi, tí wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà majẹmu tí wọn dá níwájú mi, n óo bẹ́ wọn bíi ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù tí wọn bẹ́ sí meji, tí wọ́n sì gba ààrin rẹ̀ kọjá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si ṣe awọn ọkunrin na, ti o ti ré majẹmu mi kọja, ti kò ṣe ọ̀rọ majẹmu ti nwọn ti dá niwaju mi, bi ẹgbọrọ malu ti nwọn ti ke meji, ti nwọn si kọja lãrin ipin mejeji rẹ̀,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi ó ṣe àwọn ọkùnrin náà tí ó da májẹ̀mú mi, tí kò tẹ̀lé májẹ̀mú tí wọ́n ti dá níwájú mi bí ẹgbọ̀rọ màlúù tí wọ́n gé sí méjì, tí ó sì kọjá láàrin ìpín méjì náà.