Jeremiah 34:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA, Ọlọrun Israẹli ní, kí n lọ sọ fún Sedekaya, ọba Juda pé òun OLUWA ní, “Mo ṣetán tí n óo fi ìlú yìí lé ọba Babiloni lọ́wọ́; yóo sì dáná sun ún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli, wi: Lọ, ki o si sọ fun Sedekiah, ọba Juda, ki o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi; Wò o, emi o fi ilu yi le ọwọ ọba Babeli, on o si fi iná kun u:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì ọmọ ogun wí: Lọ sí ọ̀dọ̀ Sedekáyà Ọba Júdà kí o sì sọ fún-un pé, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Èmi fẹ́ fa orílẹ̀ èdè yìí lé Ọba Bábílónì lọ́wọ́, yóò sì jó palẹ̀.