Jeremiah 34:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo fi Sedekaya, ọba Juda ati àwọn ìjòyè rẹ̀ lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn. Wọn óo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun ọba Babiloni tí ó ti ṣígun kúrò lọ́dọ̀ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati Sedekiah, ọba Juda, ati awọn ijoye rẹ̀ li emi o fi le ọwọ awọn ọta wọn, ati le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn, ati le ọwọ ogun ọba Babeli, ti o ṣi lọ kuro lọdọ nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Sédékáyà Ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ ní Júdà ni èmí yóò fi lé àwọn ọ̀ta wọn lọ́wọ́, àti àwọn tí ń wá ẹ̀mí wọn àti lé ọwọ́ ogun Bábílónì tí ó ti lọ kúrò lọ́dọ̀ yín.