Jeremiah 34:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ wò ó, n óo pàṣẹ, n óo sì kó wọn pada sí ìlú yìí, wọn yóo gbógun tì í, wọn yóo gbà á; wọn yóo sì dáná sun ún. N óo sọ àwọn ìlú Juda di ahoro, kò ní sí eniyan tí yóo máa gbé inú wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wò o, emi o paṣẹ, li Oluwa wi: emi o si mu wọn pada si ilu yi; nwọn o si ba a jà, nwọn o si kó o, nwọn o si fi iná kún u: emi o si ṣe ilu Juda li ahoro laini olugbe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wò ó èmi ó pàṣẹ ni OLÚWA wí, èmi ó sì mú wọn padà sí ìlú yìí, wọn ó sì baà jà, wọn ó sì kóo, wọn ó fi iná jóo. Èmi ó sì sọ ìlú Júdà dí ahoro.”