Jeremiah 34:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sedekaya, o kò ní sá àsálà, ṣugbọn wọn óo mú ọ, wọn óo fà ọ́ lé Nebukadinesari lọ́wọ́, ẹ óo rí ara yín lojukooju, ẹ óo bá ara yín sọ̀rọ̀, o óo sì lọ sí Babiloni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ kì o si le sala kuro lọwọ rẹ̀, ṣugbọn ni mimú a o mu ọ, a o si fi ọ le e lọwọ; oju rẹ yio si ri oju ọba Babeli, on o si ba ọ sọ̀rọ lojukoju, iwọ o si lọ si Babeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ kò ní sá àsálà, ṣùgbọ́n à ó mú ọ, bẹ́ẹ̀ ni a ó sì fà ọ́ lé e lọ́wọ́. Ìwọ yóò rí Ọba Bábílónì pẹ̀lú ojú ara rẹ; yóò sì bá ọ sọ̀rọ̀ lójúkojú; ìwọ yóò sì lọ sí Bábílónì.