Jeremiah 34:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ní àkókò tí àwọn ọmọ ogun ọba Babiloni gbógun ti Jerusalẹmu ati Lakiṣi ati Aseka, nítorí pé àwọn nìkan ni wọ́n ṣẹ́kù ninu àwọn ìlú olódi Juda.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni wakati na ogun ọba Babeli mba Jerusalemu jà, ati gbogbo ilu Juda ti o kù, Lakiṣi, ati Aseka: wọnyi li o kù ninu ilu Juda, nitori nwọn jẹ ilu olodi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ogun Ọba Bábílónì ń bá Jérúsálẹ́mù jà, àti gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tí ó kù ní Júdà, Lákíṣì, Ásékà; àwọn nìkan ni ìlú olódi tí ó kù ní Júdà.