Jeremiah 35:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo ti rán gbogbo àwọn iranṣẹ mi, àwọn wolii, si yín, ní ọpọlọpọ ìgbà pé kí olukuluku yín yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú tí ó ń tọ̀, kí ẹ tún ìwà yín ṣe, kí ẹ má sá tẹ̀lé àwọn oriṣa kiri, kí ẹ yé máa sìn wọ́n; kí ẹ lè máa gbé ilẹ̀ tí mo fún ẹ̀yin ati àwọn baba ńlá yín. Ṣugbọn ẹ kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi si ti rán gbogbo awọn iranṣẹ mi, awọn woli, si nyin pẹlu, emi dide ni kutukutu, mo ran wọn wipe, Ẹ yipada nisisiyi, olukuluku kuro ni ọ̀na buburu rẹ̀, ki ẹ si tun iṣe nyin ṣe rere, ki ẹ máṣe tọ̀ awọn ọlọrun miran lẹhin lati sin wọn, ẹnyin o si ma gbe ilẹ na ti mo ti fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin; ṣugbọn ẹnyin kò tẹ eti nyin, bẹ̃ni ẹnyin kò si gbọ́ temi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ àti àwọn wòlíì mí sí yín pẹ̀lú wí pé, “Ẹ yípadà nísisiyìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín, kí ẹ sì tún ìṣe yín ṣe sí rere. Kí ẹ ma sì ṣe bọ òrìṣà tàbí sìn wọ́n; ẹ̀yin ó sì máa gbé ní ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín àti fún àwọn baba ńlá yín.” Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sími.