Jeremiah 35:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ni mo sọ pé n óo jẹ́ kí ibi bá àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu, nítorí pé mo bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kò gbọ́; mo pè wọ́n, wọn kò dáhùn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi pe, Wò o, emi o mu wá sori Juda, ati sori gbogbo olugbe Jerusalemu, gbogbo ibi ti emi ti sọ si wọn; nitori ti emi ti ba wọn sọ̀rọ, nwọn kò si gbọ́; mo si ti pè wọn, nwọn kò si dahùn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà, báyìí ni, OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Fetísílẹ̀! Èmi ó mú gbogbo ohun búburú tí èmi ti sọ wá sórí Júdà, àti sórí gbogbo olùgbé Jérúsálẹ́mù nítorí èmi ti bá wọn sọ̀rọ̀: Ṣùgbọ́n wọn kò sì dáhùn.’ ”