Jeremiah 35:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Jeremaya sọ fún àwọn ọmọ Rekabu pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Nítorí pé ẹ gbọ́ràn sí Jonadabu baba ńlá yín lẹ́nu, ẹ sì pa gbogbo òfin rẹ̀ mọ́, ẹ sì ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ pé kí ẹ máa ṣe,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jeremiah si wi fun ile awọn ọmọ Rekabu pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Nitori ti ẹnyin gbà ofin Jonadabu, baba nyin gbọ́, ti ẹnyin si pa gbogbo ilana rẹ̀ mọ, ti ẹ si ṣe gẹgẹ bi eyi ti o ti palaṣẹ fun nyin:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Jeremáyà wí fún ìdílé Rékábù pé, “Báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé: ‘Nítorí tí ẹ̀yin gba òfin Jónádábù baba yín, tí ẹ sì pa gbogbo rẹ̀ mọ́, tí ẹ sì ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó palásẹ fún un yín.’