Jeremiah 36:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Baruku bá ka ọ̀rọ̀ Jeremaya tí ó kọ sinu ìwé, sí etígbọ̀ọ́ gbogbo eniyan ní yàrá Gemaraya, ọmọ Ṣafani, akọ̀wé, tí ó wà ní gbọ̀ngàn òkè ní Ẹnu Ọ̀nà Titun ilé OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Baruku si ka ọ̀rọ Jeremiah lati inu iwe ni ile Oluwa, ni iyara Gemariah, ọmọ Ṣafani, akọwe, ni àgbala oke, nibi ilẹkun ẹnu-ọ̀na titun ile Oluwa li eti gbogbo enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti inú yàrá Gémáríà ọmọ Sáfánì akọ̀wé, ní àgbàlá òkè níbi ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà ilé OLÚWA tuntun. Bárúkì sì ka ọ̀rọ̀ Jeremáyà láti inú ìwé ní ilé OLÚWA sí etí gbogbo ènìyàn.