Jeremiah 36:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó lọ sí yàrá akọ̀wé ní ààfin ọba, ó bá gbogbo àwọn ìjòyè tí wọn jókòó níbẹ̀: Eliṣama akọ̀wé ati Delaaya ọmọ Ṣemaaya, ati Elinatani ọmọ Akibori, ati Gemaraya ọmọ Ṣafani, ati Sedekaya ọmọ Hananaya ati gbogbo àwọn ìjòyè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si sọkalẹ lọ si ile ọba, sinu iyara akọwe, si wò o, gbogbo awọn ijoye joko nibẹ, Eliṣama, akọwe, ati Delaiah, ọmọ Semaiah, ati Elnatani, ọmọ Akbori, ati Gemariah, ọmọ Safani, ati Sedekiah, ọmọ Hananiah, ati gbogbo awọn ijoye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé Ọba sínú yàrá akọ̀wé; níbi tí gbogbo àwọn ìjòyè gbé jókòó sí: Élísámà akọ̀wé, Déláyà ọmọ Sámáyà, Elinátanì ọmọ Ákíbórì, Gémáríà ọmọ Sáfánì àti Sedekáyà ọmọ Hananáyà àti gbogbo àwọn ìjòyè.