Jeremiah 36:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo àwọn ìjòyè bá rán Jehudi ọmọ Netanaya, ọmọ Ṣelemaya ọmọ Kuṣi pé kí ó lọ sọ fún Baruku kí ó máa bọ̀ kí ó sì mú ìwé tí ó kà sí etígbọ̀ọ́ gbogbo eniyan lọ́wọ́. Baruku, ọmọ Neraya, sì wá sọ́dọ̀ wọn tòun ti ìwé náà lọ́wọ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni gbogbo awọn ìjoye rán Jehudu, ọmọ Netaniah, ọmọ Ṣelemiah, ọmọ Kuṣi, si Baruku wipe, Mu iwe-kiká na li ọwọ rẹ, lati inu eyiti iwọ kà li eti awọn enia, ki o si wá. Nigbana ni Baruku, ọmọ Neriah, mu iwe-kiká na li ọwọ rẹ̀, o si wá si ọdọ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ìjòyè sì rán Jéhúdù ọmọ Métamáyà ọmọ Sélémáyà ọmọ Kúsì sí Bárúkì wí pé, mú ìwé kíká náà ní ọwọ́ rẹ láti inú èyí tí ìwọ kà ní etí àwọn ènìyàn; kí o si wá. Nígbà náà ni Bárúkì ọmọ Nétayà wá sí ọ̀dọ̀ wọn pẹ̀lú ìwé kíká ní ọwọ́ rẹ̀.