Jeremiah 36:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Baruku bá dá wọn lóhùn pé, Jeremaya ni ó sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún òun ni òun fi kọ ọ́ sinu ìwé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Baruku si da wọn lohùn pe; Lati ẹnu rẹ̀ li o si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun mi, emi si fi tadawa kọ wọn sinu iwe na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bárúkì sì dá wọn lóhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, láti ẹnu rẹ̀ ni, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ báyìí fún mi, èmi sì fi tàdáwà kọ wọ́n sínú ìwé náà.”