Jeremiah 36:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Mú ìwé kíká kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún ọ nípa Israẹli ati Juda ati gbogbo orílẹ̀-èdè sinu rẹ̀. Gbogbo ohun tí mo sọ láti ọjọ́ tí mo ti ń bá ọ sọ̀rọ̀ ní ìgbà ayé Josaya títí di òní, ni kí o kọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mu iwe-kiká fun ara rẹ̀, ki o si kọ sinu rẹ̀, gbogbo ọ̀rọ ti emi ti sọ si Israeli, ati si Juda, ati si gbogbo orilẹ-ède, lati ọjọ ti mo ti sọ fun ọ, lati ọjọ Josiah titi di oni yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Mú ìwé kíká fún ará rẹ, kí o sì kọ sínú rẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ nípa Ísírẹ́lì àti ti Júdà, àti sí gbogbo orílẹ̀ èdè láti ìgbà tí mo ti sọ fún ọ láti ọjọ́ Jòsáyà títí di òní.