Jeremiah 36:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ìjòyè bá fi ìwé náà pamọ́ sinu yàrá Eliṣama akọ̀wé, lẹ́yìn náà wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ ọba ní gbọ̀ngàn, wọ́n sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wọle tọ̀ ọba lọ ninu àgbala, ṣugbọn nwọn fi iwe-kiká na pamọ si iyara Eliṣama, akọwe, nwọn si sọ gbogbo ọ̀rọ na li eti ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn tí wọ́n fi ìwé kíkà náà pamọ́ sí iyàrá Elisámà akọ̀wé, wọ́n sì wọlé tọ Ọba lọ nínú àgbàlá, wọ́n sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà ní etí Ọba.