Jeremiah 36:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọba bá rán Jehudi pé kí ó lọ mú ìwé náà wá, ó sì mú un wá láti inú yàrá Eliṣama, akọ̀wé. Jehudi bá kà á fún ọba ati gbogbo àwọn ìjòyè tí wọn dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si rán Jehudu lati lọ mu iwe-kiká na wá: on si mu u jade lati inu iyara Eliṣama, akọwe. Jehudu si kà a li eti ọba, ati li eti gbogbo awọn ijoye, ti o duro tì ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì rán Jéhúdù láti lọ mú ìwé kíká náà wá láti inú iyàrá Elisámà akọ̀wé. Ó sì ka ìwé náà ní etí Ọba àti ní etí gbogbo àwọn ìjòyè tí ó dúró ti Ọba.