Jeremiah 36:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí Jehudi bá ti ka òpó mẹta tabi mẹrin ninu ìwé náà, ọba yóo fi ọ̀bẹ gé e kúrò, yóo sì jù ú sinu iná tí ń jó níwájú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe títí ó fi fi ìwé náà jóná tán.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati Jehudu ti kà ewe mẹta tabi mẹrin, ọba fi ọbẹ ke iwe na, o si sọ ọ sinu iná ti o wà ninu idaná, titi gbogbo iwe-kiká na fi joná ninu iná ti o wà lori idaná.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Jéhúdù ka ojú ìwé mẹ́ta sí mẹ́rin nínú ìwé náà, Ọba fi ọ̀bẹ gé ìwé, ó sì sọ sínú iná tí ó wà nínú ìdáná, títí tí gbogbo ìwé náà fi jóná tán.