Jeremiah 36:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn tí ọba ti fi ìwé náà jóná, ati gbogbo ohun tí Jeremaya ní kí Baruku kọ sinu rẹ̀, OLUWA sọ fún Jeremaya pé,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá, lẹhin ti ọba ti fi iwe-kiká na ati ọ̀rọ ti Baruku kọ lati ẹnu Jeremiah wá joná, wipe,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn tí Ọba fi ìwé kíkà náà tí ọ̀rọ̀ tí Bárúkì kọ láti ẹnu Jeremáyà jóná tán, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì tọ Jeremáyà wá: