Jeremiah 36:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, ohun tí èmi OLUWA níí sọ nípa rẹ̀ ni pé, ẹyọ ọmọ rẹ̀ kan kò ní jọba lórí ìtẹ́ Dafidi. Ìta ni a óo gbé òkú rẹ̀ jù sí, oòrùn yóo máa pa á lọ́sàn-án, ìrì yóo sì máa sẹ̀ sí i lórí lóru.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi li Oluwa wi niti Jehoiakimu, ọba Juda, pe, On kì yio ni ẹniti yio joko lori itẹ Dafidi: a o si sọ okú rẹ̀ nù fun oru li ọsan, ati fun otutu li õru.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA wí níti Jéhóíákímù Ọba Júdà pé: Òun kì yóò ní ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì, à ó sì sọ òkú rẹ̀ nù fún ooru ní ọ̀sán àti fún òtútù ní òru.