Jeremiah 36:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo jẹ òun, ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ níyà, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. N óo mú kí gbogbo ibi tí mo pinnu lórí wọn ṣẹ sí wọn lára ati sí ara àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn ará Juda, nítorí pé wọn kò gbọ́ràn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si jẹ on, ati iru-ọmọ rẹ̀, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ niya, nitori aiṣedede wọn; emi o si mu wá sori wọn, ati sori awọn olugbe Jerusalemu, ati sori awọn ọkunrin Juda, gbogbo ibi ti emi ti sọ si wọn, ṣugbọn nwọn kò gbọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi ó sì jẹ òun àti irú ọmọ rẹ̀, ìránṣẹ́ rẹ̀ níyà nítorí àìṣedédé wọn; èmi ó sì mú gbogbo ibi tí èmi ti sọ sí wọn wá sórí wọn, àti sórí àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù àti àwọn ènìyàn Júdà, nítorí tí wọn kò fetísí mi.’ ”