Jeremiah 36:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jeremaya bá fún Baruku akọ̀wé, ọmọ Neraya, ní ìwé mìíràn, Baruku sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jeremaya sọ fún un sinu rẹ̀. Ó kọ ohun tí ó wà ninu ìwé àkọ́kọ́ tí Jehoiakimu ọba Juda fi jóná, ó sì fi àwọn nǹkan mìíràn kún un pẹlu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Jeremiah mu iwe-kiká miran, o si fi i fun Baruku, akọwe, ọmọ Neriah; ẹniti o kọwe sinu rẹ̀ lati ẹnu Jeremiah gbogbo ọ̀rọ iwe ti Jehoiakimu, ọba Juda ti sun ninu iná: a si fi ọ̀rọ pupọ bi iru eyi kún ọ̀rọ iwe na pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Jeremáyà mú ìwé kíká mìíràn fún Bárúkì akọ̀wé ọmọ Neráyà, ẹni tí ó kọ̀wé sínú rẹ̀ láti ẹnu Jeremáyà gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé tí Jéhóíákímù Ọba Júdà ti sun níná. A sì fi onírúurú ọ̀rọ̀ bí irú èyí kún pẹ̀lú.