Jeremiah 36:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jeremaya bá pe Baruku ọmọ Neraya, ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí OLUWA bá a sọ fún un, Baruku bá kọ wọ́n sinu ìwé kíká kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Jeremiah pè Baruku, ọmọ Neriah; Baruku si kọ lati ẹnu Jeremiah gbogbo ọ̀rọ Oluwa ti o ti sọ fun u, sori iwe-kiká na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Jeremáyà pe Bárúkì ọmọ Neráyà, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run báa sọ fún, Bárúkì sì kọ láti ẹnu Jeremáyà, gbogbo ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó ti sọ fún-un sórí ìwé kíká náà.