Jeremiah 36:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
nítorí náà, ìwọ ni óo lọ sibẹ ní ọjọ́ ààwẹ̀ láti ka ọ̀rọ̀ tí o gbọ́ ní ẹnu mi; tí o sì kọ sí inú ìwé kíká, sí etí gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n wá láti ìlú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina iwọ lọ, ki o si kà ninu iwe-kika na, ti iwọ kọ lati ẹnu mi wá, ọ̀rọ Oluwa li eti awọn enia ni ile Oluwa li ọjọ ãwẹ: ati pẹlu, iwọ o si kà a li eti gbogbo Juda, ti nwọn jade wá lati ilu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, ìwọ lọ sí ilé OLÚWA ní ọjọ́ ààwẹ̀, kí o sì kà nínú ìwé kíkà náà ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ìwọ ti ẹnu mi kọ; ìwọ ó sì kà á ní etí gbogbo Júdà, tí wọ́n jáde wá láti ìlú wọn.